- mf Jesu, ‘Wọ oninure,
Sin wa lọ tabili Rẹ,
Si f’onjẹ ọrun bọ́ wa.
- B’a ti kunlẹ yi Ọ ka,
Jẹ k’a mọ̀ p’o sunmọ wa;
Si f’ifẹ nla Rẹ hàn ni.
- Gb’a ba nf’ igbagbọ wò Ọ,
p T’a sì nsọkun ẹṣẹ wa,
Sọ arò wa di ayọ̀.
- Gb’ a ta ba f’ẹnu kan wain,
Ti nṣapẹrẹ ẹjẹ Rẹ,
M’ọkàn wa kun fun ifẹ.
- f Fà wa sibi ìha Rẹ,
Nibiti isun nì nṣàn,
Si wẹ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ nù.
- p Jọ tu ìde ẹṣẹ wa,
Si busi igbagbọ wa,
F’ alafia Rẹ fun wa.
- Ma f’ọwọ Rẹ tọ́ wa nṣó,
Tit’ ao fi de ibugbe Rẹ,
N’ ilẹ t’o dara julọ. Amin.