- mf Ọjọ kò; ase na leyi,
Mo f’ara mi fun nyin;
p Ẹ wo, mo f’ẹjẹ mi fun nyin,
Lati rà nyin pada.
- O di ‘nu ‘jọba Baba mi,
Ki mto tun ba nyiun mu;
‘Gbana ẹkun kò ni si mọ,
A o ma yọ̀ titi
- mf Titi l’ao ma jẹ onjẹ yi,
K’o to di igba na;
Ká gbogb’ aiye l’ ọpọlọpọ
Y’o ma jẹ, y’o ma mu.
- ‘Bukun atọrunwá y’o ma
Wa lor’ awọn t’ o njẹ;
Ngo gbe or’ itẹ Baba mi
Ma pès’ àye fun wọn.
- p Ṣugbọn nisisiyi, ago
cr Kikorò l’em’ o mu,
Emi o mù nitori nyin,
pp Ago rora ikú.
- p Ẹ ko le mọ̀ banujẹ mi,
Ẹ ko ti r’ogo mi;
mf Ṣugbọn ẹ ma ṣ’eyi titi,
K’ẹ ma fi ranti mi. Amin.