- f Ọdọ Agutan Ọlọrun,
Jọ wẹ̀ mi ninu ẹjẹ Rẹ;
Sa jẹ ki nmọ ‘fẹ Rẹ, ‘gbana
Irora dùn, iku l’erè.
- f Fa ọkàn mi kuro l’aiye,
K’ o jẹ k’o ṣe Tirẹ titi;
Fì edidi Rẹ s’ aiya mi,
Edid’ ifẹ titi aiye.
- A ! awọn wọnni ti yọ̀ to,
T’ o f’ìha Rẹ ṣe ‘sadi wọn!
Nwọn fi Ọ ṣe agbara wọn,
Nwọn njẹ, nwọn si nmu ninu Rẹ.
- mf O kùn wa loju p’Ọlọrun,
Fẹ m’ awa yi lọ sin’ ogo!
Pe, O sọ ẹrù d’ ọm’Ọba,
Lati ma jẹ fajì lailai!
- Baba, mu wa ronu jinlẹ̀,
K’ a lè mọ̀ iṣẹ nlanla Rẹ;
Má ṣai tu okùn ahọn wa,
K’ a lè sọ ibu ifẹ Rẹ.
- f Jesu, Iwọ l’olori wa,
‘Wọ l’a o tẹri wa ba fun,
‘Wọ l’ a o fi ọkàn wa fun,
B’a kù, b’a wà, k’a jẹ Tirẹ. Amin.