- p Mo nkebi on ongbẹ,
cr Jesu, ṣe onjẹ mi;
f Tu jade, om’ iyè,
Lat’ inu apata.
- p Wọ akara t’ a bù,
cr Tẹ ọkàn mi l’ọrùn,
mf B’ a ti b’ ọkàn ìye,
Bọ mi, má jẹ ki nkú.
- mp Wọ, Ajara ìye,
Jẹ ki mmọ adùn Rẹ,
cr Jọ, tùn ọkàn mi ṣe,
Fi ifẹ s’ aiya mi.
- p Ọna aikúna pọ̀,
‘Ti mo ti rìn kọja;
cr Bọ mi, Onjẹ ọrun,
di Gbà mi, Ọm’ Ọlọrun.
- mf Aginju wà sibẹ̀,
Ti y’o m’ongbẹ gbẹ mi;
f Ẹnyin Omi iyè,
Ẹ ma sun ninu mi. Amin.