- mp Li oru ibanijẹ nì,
T’ agbara isà okú nde,
S’Ọmọ iyọnu Ọlọrun,
p Ọrẹ tà A fun ọta Rẹ̀.
- Ki ‘waiyaja Rẹ̀ to bẹrẹ̀,
O mu akara, O sì bu;
Wò ifẹ n’ iṣẹ Rẹ̀ gbogbo,
Gb’ ọ̀rọ ore-ọfẹ t’O sṣ.
- p “Eyi l’ara t’a bù f’ ẹ̀ṣẹ,
Gbà, k’ẹ si jẹ onjẹ iyè;
O si mú ago, O bù wain,
Eyi majẹmu ẹjẹ Mi.
- mp O wipe, “Ṣ’ eyi tit’ opin,
cr N’ iranti ikú ọrẹ nyin;
Gba t’ ẹ ba pade, ma ranti
Ifẹ Ọlọrun nyin t’o lọ.
- Jesu, awa nyọ̀ s’asè Rẹ,
p Awa f’ikú Rẹ hàn l’orin;
K’ Iwọ to pada, ao ma jẹ
Onjẹ alẹ Ọdagutan. Amin.