- mf Gẹgẹ bi ọ̀rọ ore Rẹ,
Ninu irẹlẹ̀ nla,
Emi o ṣe yi Oluwa,
p Emi o ranti Rẹ.
- mf Ara Rẹ ti a bù fun mi,
Yio jẹ onjẹ mi;
Mo gbà ago majẹmu Rẹ,
p Lati ṣe ranti Rẹ.
- np Mo lè gbagbe Getsemane,
Ti mo r’ ijamú Rẹ,
pp Iyà on ogùn ẹjẹ Rẹ,
cr Ki nma si ranti Rẹ?
- mp Ngo ranti gbogbo ‘rora Rẹ,
At’ ifẹ Rẹ si mi;
cr Bi o kù ẹmi kan fun mi,
Emi o ranti Rẹ.
- pp ‘Gbati ẹnu mi ba pamọ,
Ti iyè mi ba ra,
cr Ti O ba de n; ijọba Rẹ.
Jesu, jọ ranti mi. Amin.