Hymn 431: Jesus, thou joy of loving hearts!

Jesu ayo okan gbogbo

  1. f Jesu ayọ̀ ọkàn gbogbo,
    Orisun ‘yè, imọlẹ wa,
    di Nin’ ọpọ bukun aiye yi,
    cr Laintẹlọrùn: a tọ wá.

  2. f Otitọ Rẹ duro lailai,
    p ‘Wọn gb’ awọn to kepè Ọ là;
    cr Awọn ti o wá Ọ, ri Ọ.
    f Bi gbogbo nin’ ohun gbogbo.

  3. mf A tọ Ọ wò, Onjẹ Iyè,
    A fẹ jẹ l’ara Rẹ titi;
    A mu ninu Rẹ, Orisun,
    Lati pa ongbẹ ọkàn wa.

  4. p Ongbẹ Rẹ sa ngbẹ ọkàn wa,
    Nibikibi t’o wù k’ a wà;
    cr ‘Gbat’ a ba ri Ọ awa yọ̀,
    f A yọ̀ nigbat’ a gbà Ọ gbọ́.

  5. mp Jesu, wá ba wa gbe titi,
    Ṣe akokò wa ni rere;
    cr Le okunkun ẹ̀ṣẹ kuro,
    f Tàn ‘mọlẹ̀ Rẹ mimọ́ s’aiye. Amin.