- mf “Mo nlọ; talaka Mi mbẹ lọdọ nyin,
Ẹ lè ma ṣore fun wọn b’ẹ ti nfẹ.”
- mp Eyi ni ogùn t’Olugbala wa
Fi silẹ f’ awọn Tirẹ̀, k’o to lọ:
- Wura on júfù kọ, òtoṣi ni,
K’a ma ràn wọn lọwọ nitori Rẹ̀.
- mp Ẹrù nla kọ, ogún t’o l’ọrọ̀ ni
Kọ ni talaka at’ aṣagbe wa?
- Ohùn irora awọn t’iya njẹ,
Kò ha nke si wa lati f’ anu hàn?
- Ọkàn t’o gb’ọgbẹ, ọkàn ti nṣiṣẹ́;
Ẹkun opó, at’ alaini baba!
- cr On t’o f’ara Rẹ̀ fun wa, sì ti fi
Etù ọrun f’ awa iranṣẹ Rẹ̀.
- Kò s’otoṣi kan ti kò le ṣajò,
F’ẹni tòṣi ju lọ; agbara ni.
- Isin mimọ ailabawọn l’eyi.
Ti Baba mbere lọwọ gbogbo wa. Amin.