- f Yìn Ọlọrun, yin lailai
Fun ifẹ ojojumọ;
Orisun ayọ̀ gbogbo,
K’ìyìn Rẹ̀ gb’ẹnu wa kan.
- mf Fun irè t’oko nmú wà;
Fun onjẹ t’a nmù l’ọgba;
Fun eso igì pẹlu;
At’ororo ti a nlò,
- Fun gbogb’ ẹran ọ̀sin wa
T’on ṣiri ọkà gbigbó;
Ọrun ti nsẹ̀ ‘rì silẹ;
Orùn ti nm’ oru rẹ̀ wá.
- Gbogbo nkan t’ẹrun nmu wá
Kakiri gbogbo ilẹ;
At’ eso ìgba òjo
Lat’ inu ẹ̀kún rẹ̀ wá.
- f ‘Wọ l’ẹlẹbùn gbogbo wọn
Orisun ibukun wa;
‘Torina ọkàn wa y’o
F’ iyin at’ ọpẹ fun Ọ.
- mp Ijì lile iba jà
K’o ba gbogbo ọkà jẹ;
K’eso igi wọ́ dànu
Ki akoko rẹ̀ to pe;
- Ajara ‘ba má so mọ́,
Ki igi gbogbo sì gbẹ,
K’ẹran ọ̀sin gbogbo kú
K’ẹran igbẹ tán pẹlu;
- mf Sibẹ, Iwọ l’ọkàn wa
Y’o f’iyìn at’ọpẹ fun;
Gbat’ ibukun gbogbo tan
cr Ao sa fẹ Ọ fun ‘ra Rẹ. Amin.