Hymn 429: O Fount of good, for all your love

Wo orison ohun rere

  1. mf ‘Wọ orisun ohun rere,
    Awa fẹ ṣe ‘fẹ rẹ;
    Ohun wo l’a lè fi fun Ọ,
    Ọba gbogbo aiye?

  2. p L’aiye yi, ‘Wọ ní otoṣi,
    T’o jẹ enia Rẹ:
    Orukọ wọn n’Iwọ njẹwọ
    Niwaju Baba Rẹ.

  3. p ‘Gba nwọn ba nke n’ inira wọn,
    Ohun Rẹ l’ awa ngbọ́;
    ‘Gba ba si nṣe itọju wọn,
    Awa nṣe ‘tọju Rẹ.

  4. f Jesu, má ṣai gbà ọrẹ wa,
    Si f’ ibukun Rẹ si;
    Ma f’ ibukun Rẹ s’ ẹbùn wa,
    Fun awọn t’a nfi fun.

  5. Fun Baba, Ọmọ at’ Ẹmi,
    Ọlọrun ti a nsìn;
    f Ni ki a ma fi ogo fun,
    Titi aiyeraiye. Amin.