- f Ohun t’a fi fun Ọ,
Tirẹ ni Oluwa:
Gbogbo ohun ti a sì ni.
Ọwọ Rẹ l’o ti wá.
- mf Jẹ k’ a gba ẹ̀bun Rẹ,
Bi iriju rere:
Bi O sì ti mbukun wa to,
Bẹ l’a o fi fun Ọ.
- p Ọpọ ni iṣẹ́ nṣẹ́,
Ti nwọn kò r’ onjẹ jẹ;
Ọpọ l’o si ti ṣako lọ,
Kuro l’agbo Jesu.
- cr K’ a ma tù ni ninu,
K’ a mà rẹ̀ ni l’ẹkún,
K’ a ma bọ́ alainibaba,
N’ iṣẹ t’ à ba ma ṣẹ.
- mf K’ a tú ondè silẹ̀,
K’ a f’ ọ̀na ìye hàn,
K’ a kọ ni l’ ọna Ọlọrun,
B' iwa Kristi l' o ri
- cr A gba ọ̀rọ Rẹ gbọ́,
di Busi igbagbọ wa;
f Ohun t’ a ṣe fun ẹni Rẹ,
Jesu, a ṣe fun Ọ. Amin.