- f Oluwa ọrun on aiye,
‘Wọ n’ìyin at’ọpẹ yẹ fun;
Bawo l’a ba ti fẹ Ọ to,
Onibu ọrẹ?
- Orun ti nràn, at’ afẹfẹ,
Gbogbo eweko nsọ ‘fẹ Rẹ;
‘Wọ l’O nmu irugbin dara,
Onibu ọrẹ?
- Fun ara lile wa gbogbo,
Fun gbogbo ibukun aiye,
Awa yin Ọ, a si dupẹ,
Onibu ọrẹ?
- p O kò dù wa li Ọmọ Rẹ,
O fi fun aiye ẹ̀ṣẹ wa,
O so f’ẹbun gbogbo pẹlu,
Onibu ọrẹ?
- mf O fun wa l’Ẹmi Mimọ́ Rẹ.
Ẹmi iye at’ agbara,
O rọ̀jo ẹkún bukun Rẹ
Le wa lori.
- p Fun idariji ẹ̀ṣẹ wa,
cr Ati fun ireti ọrun,
f Kil’ ohun t’ a ba fi fun Ọ?
Onibu ọrẹ.
- mf Owo ti à nná, òfo ni,
Ṣugbọn eyi t’a fi fun Ọ,
O jẹ iṣura tit’ aiye,
Onibu ọrẹ.
- Ohun t’a bùn Ọ, Oluwa,
cr Wọ o sàn le pada fun wa;
f Layọ l’a o ta Ọ lọrẹ.
Onibu ọrẹ.
- Ni ọdọ Rẹ lati ṣàn wa,
Ọlọrun Olodumare;
p Jẹ k’a lè ba Ọ gbe titi,
Onibu ọrẹ. Amin.