- mf Jesu, ba Ijọ Rẹ gbe,
Ṣamọna at’ odi rẹ̀,
B’o ti nlà ‘danwo kọja;
Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- mf F’ọwọ ifẹ Rẹ yi ka,
Dabobo lọwọ ọta,
Tu ninu nigba ibi;
p Awa mbẹ Ọ, gbo tiwa.
- mf M’ẹkọ at’ ìwa rẹ̀ mọ́;
Jẹ k’o fi suru duro;
K’o simi le ‘leri Rẹ;
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- mf Pẹlu rẹ̀ lọjọ gbogbo,
K’o bọ̀ lọjọ gbogbo,
K’o ma ṣiṣẹ fun yìn Rẹ;
p Awa, bẹ Ọ, gbo tiwa.
- cr K’ohùm rẹ̀ ma já goro,
N’ikilọ ‘dajọ ti mbọ̀;
Ni sisọ ifẹ Jesu:
p Awa mbẹ Ọ, gbo tiwa.
- mf Wa tun ibajẹ rẹ̀ ṣe,
Wa tun Tempili Rẹ kọ́,
Fi ara Rẹ hàn nibẹ.
Awa mbẹ̀ Ọ, gbọ́ tiwa.
- cr Wá dá gbogbo ide rẹ̀
Mu ‘lara at’ ìja tan,
M’alafia ọrun wa,
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- mf Mu gbogbo ọ̀ràn rẹ̀ tó;
Ma jẹ k’ọwọ Eṣu tẹ;
Ki aiye ma le tan jẹ;
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- cr K’ẹkọ rẹ̀ jẹ ọkanna,
N’nu otitọ at’ifẹ;
K’o fà ọ̀pọ s’ igbagbọ;
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- mf K’o ma tọju alaini,
K’o si ma wá aṣako,
At’ onirobinuje;
p Awa mbẹ̀ Ọ, gbọ̀ tiwa.
- mf Ma jẹ k’ifẹ rẹ̀ tutu,
M’awọn oluṣọ gboìya,
S’agbàrà y’agbo Rẹ ka:
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- mf K’ awọn alufa ma bọ;
Ki nwọn j’ oluṣọ totọ,
Lati ma tọ́ Ijọ Rẹ.
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- mf Ki nwọn ṣe bi nwọn ti nsọ,
K’ nwọn f’apẹrẹ mimọ hàn
Bi aṣaju agbo Rẹ,
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- F’ or’ọfẹ Ẹnit’ o ku
At’ ifẹ Baba ba gbe;
K’Ẹmi ma ṣàmọna rẹ̀;
Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- mf Wẹ̀ gbogbo àrun rẹ̀ nù;
L’ẹ̀ru on ‘yemeji lọ,
Mu ‘ṣẹgun rẹ̀ de kánkán.
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- p Ran lọwọ nigba awẹ̀,
cr Tit’ iṣẹ rẹ̀ o pari,
f T’ Ọkọ-yawo y’o si de:
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- ff Nigbana k’O ṣe logo,
Ati ni ailabawọn,
L’ẹwà didan t’o yẹ Ọ,
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa.
- ff Mu yẹ, ki on ba le pin
N’nu àye t’ Iwọ npèse;
Lai, k’o n’ibukun nibẹ.
p Awa mbẹ Ọ, gbọ tiwa. Amin.