- f Ẹ wá k’ a da orin wa pọ̀
Mọ t’awọn Angẹli;
Ẹgbẹgbẹrun ni ohùn wọn,
Ọkan ni ayọ̀ wọn.
- Nwọn nkọrin pe, “Ọla nla ye
Ọdagutan t’a pa:”
K’ a gberin pe, “Ọla nla yẹ:’
p ‘Tori O kú fun wa.
- mf Jesu, li O yẹ lati gba,
Ọla at’ agbara:
cr K’ ìyin t’ẹnu wa kò lè gbà,
Jẹ Tirẹ, Oluwa.
- f K’awọn t’o wà loke ọrun,
At’ ilẹ, at’ okun;
Dapọ lati gb’ogo Rẹ ga,
Jumọ yin ọla Rẹ.
- ff Ki gbogbo ẹda d’ohùn pọ̀,
Lati yìn orukọ
Ẹnit’ o joko lor’itẹ́,
Ki nwọn si wolẹ̀ fun. Amin.