f Baba, niwaju itẹ Rẹ, L’angẹli ntẹriba; Nigbagbogbo niwaju Rẹ, Ni nwọn nkọrin iyìn; di Nwọn si nfi ade wura wọn, Lelẹ yitẹ na ka; cr Nwọn nfi ohùn pẹlu duru Kọrin si Oluwa.
mf Didan Oṣumare si nstàn Si ara iyẹ wọnn; cr Bi Seraf ti nke si Seraf, Ti nwọn nkọrin ‘yin Rẹ; p Bi a ti kunlẹ nihinyi, Ran ore Rẹ si wa; K’a mọ̀ pe ‘Wọ wà nitosi, Lati da wa lohùn.
mf Nihin, nibit’ awọn Angẹl Nwò wa b’a ti nsin Ọ; cr Kọ́ wa k’a wá ile ọrun, K’a sin Ọ bi ti wọn; f K’a ba wọn kọ orin iyin, K’a ba wọn mo ‘fẹ Rẹ; Titi agbara y’o fi di Tirẹ, Tirẹ nikan. Amin.