- mf “Tani o gbe Jakọb dide?”
Ọrẹ́ Jakọb kò pọ̀;
Eyi t’o jẹ ‘yanu ni pe,
Imọ̀ wọn kò ṣọkan.
- mf “Tani o gbe Jakọb dide?”
Ọta Jakọb n’ ipá;
f Mo r’ayọ̀ ‘ṣẹgun l’oju wọn,
p Nwọn ni, “o pari fun.”
- mf “Tani o gbe Jakọb dide?”
A ha r’ẹni le wi?
p Ẹka t’o rọ nibulẹ yi,
cr O ha tun le yè mọ?
- mf “Oluwa mi, iṣẹ Rẹ ni!”
Kò s’ẹni t’o le ṣe;
p Sẹ b’ìri s’ori Jakọbu,
f On yio si tun yè. Amin.