- f Alabukun n’nu Jesu
Ni awọn ọm’Ọlọrun,
Ti a fi ẹjẹ Rẹ̀ rà
f Lat’ inu iku s’iyè;
cr A ba jẹ kà wa mọ wọn,
L’aiye yi, ati l’ọrun.
- f Awọn ti a da l’are
Nipa ore-ọfẹ Rè;
A wẹ̀ gbogbo ẹṣẹ wọn,
Nwọn o bọ́ l’ọjọ ‘dajọ;
cr A ba jẹ kà wa, &c.
- f Nwọn ns’eso ore-ọfẹ;
Ninu iṣẹ ododo,
Irira l’ẹṣẹ si wọn,
Ọr’Ọlọrun ngb ‘nu wọn;
cr A ba jẹ kà wa, &c.
- mp Nipa ẹj’Ọdagutan,
Nwọn mba Ọlọrun kẹgbẹ,
Pẹlu Ọla-nla Jesu,
A wọ̀ wọn l’aṣọ ogo;
cr A ba jẹ kà wa, &c. Amin.