Hymn 421: Hark! hark, my soul! angelic songs are swelling

Gbo, okan mi, bi Angeli ti nkorin

  1. mf Gbọ. ọkàn mi, bi Angẹli ti nkọrin,
    Yika ọrun ati yika aiye;
    Ẹ gbọ bi ọ̀rọ orin wọn ti dùn to!
    Ti nsọ gbati ẹṣẹ kì y’o si mọ:
    p Angẹli Jesu, angẹl ‘mọlẹ,
    cr Nwọn nkọrin ayọ̀ pade èro l’ọna.

  2. f B’a si ti nlọ, bẹ l’a si ngbọ orin wọn,
    p Wa, alarẹ̀, Jesu l’o ni k’ẹ wa;
    cr L’okunkun ni a ngbọ orin didun wọn,
    mp Ohuǹ orin wọn ni nfọnahan wa,
    p Angẹli Jesu, &c.

  3. p Ohùn Jesu ni a ngbọ l’ọna réré,
    Ohun na ndún b’agogo y’aiye ka,
    cr Ẹgbẹgbẹrun awọn t’o gbọ́ ni sì mbọ̀:
    Mu wọn w’ọdọ Rẹ, Olugbala wa.
    p.cr Angẹli Jesu, &c.

  4. mf Isimi de, bi wàhala tilẹ pọ̀,
    Ilẹ y’o mọ, lẹhin okùn aiye;
    cr Irin ajo pari f’awọn alarẹ,
    Nwọn o d’ọrun, ‘bi ‘simi nikẹhin;
    p.cr Angẹli Jesu, &c.

  5. f Ma kọrin nṣo, ẹnyin Angẹli rere,
    Ẹ ma kọrin didun k’a ba ma gbọ;
    cr Tit’ ao fi nù omije oju wa nù:
    Ti a o si ma yọ̀ titi lailai:
    p Angẹli Jesu, angẹl ‘mọlẹ,
    ff Nwọn nkọrin ayọ̀ pade èro l’ọna.