Hymn 420: Head of the Church triumphant

Olori Ijo t’ orun

  1. f Olori ijọ t’ọrun,
    L’ayọ̀ l’a wolẹ̀ fun Ọ;
    K’O to de, ijọ t’aiye,
    Y’o ma kọrin bi t’ọrun,
    ff A gbe ọkàn wa s’okè,
    Ni ‘reti t’ o ni ‘bukun;
    Awa kigbẹ, awa f’iyin
    F’Ọlọrun igbala wa.

  2. p ‘Gbat’ a wà ninu pọnju,
    T’a nkọja ninu ina,
    cr Orin ifẹ l’awa o kọ,
    Ti o nmu wa sunmọ Ọ;
    f Awa ṣapẹ, a si yọ̀,
    Ninu ojurere Rẹ;
    ff Ifẹ t’o sọ wa di Tirẹ,
    Y’o ṣe wa ni Tirẹ lai.

  3. p Iwọ mu awọn enia Rẹ
    Kọja iṣàn idanwo;
    cr A ki o bẹru wahala,
    T’ori O wà nitòsi:
    mf Aiye, ẹ̀ṣẹ, at’ Eṣu,
    Kọjuja si wa lasan,
    f L’agbara Rẹ, a o ṣẹgun,
    Ao si kọ orin Mose.

  4. mf Awa f’igbagbọ r’ogo,
    T’o tun nfẹ fi wa si;
    cr A kẹgàn aiye tori
    Ere nla iwaju wa.
    p Bi O ba si kà wa yẹ,
    Awa pelu Stefen t’o kú,
    f Y’o ri Ọ bi O ti duro,
    Lati pè wa lọ s’ọrun. Amin.