mf Oluwa ‘kore, ‘Wọ l’a nyìn; Ileri Rẹ ‘gbani kò yẹ̀; Oriṣi ìgba sì nyipo, Ọdọdun kun fun òre Rẹ; Lọjọ oni, awa dupẹ; Jẹ k’ iyin gbà ọkàn wa kan.
mf B’ akoko ‘rugbin mu wa yò; B’ ìgba ẹ̀run nmu oru wá; ‘Gbat; ọwọ òjo ba nrinlẹ̀; Tab’igbat’ ikore ba pón, f ‘Wọ, Ọba wa l’a o má yiǹ; ‘Wọ l’ alakoso gbogbo wọn.
f Jù gbogbo rẹ̀ lọ, nigbati Ọwọ Rẹ fùn ọ̀pọ ka ‘lẹ; Gbat’ ohùn ayọ̀ gbilẹkan, B’ẹda ti nko irè wọn jọ; ff Awa, pẹlu y’o má yìn Ọ Ore Rẹ ni gbogbo wa npin.
mf Oluwa ‘kore, Tirẹ ni Ojo ti nrọ̀, orùn ti nràn; Irugbìn ti a gbìn silẹ, Tirẹ l’ ọgbọn ti nmu dagba; Ọtun lẹbun Rẹ l’ ọdọdun; Ọtun n’iyin Rẹ l’ẹnu wa. Amin.