- mf Ọba awọn ẹni mimọ
T’o mọ̀ ‘ye awọn ‘rawọ;
Ọpọ enit’ ẹda gbagbe
Wà yika itẹ Rẹ lai;
- mf ‘Mọlẹ ti kuku aiye bò,
Ntàn ‘mọlẹ roro loke,
Nwọn jẹ ọm’-alade lọrun,
Ẹda gbagbe wọn laiye.
- mf Lala at’ ìya wọn fun Ọ,
Ẹda kò rohin rẹ̀ mọ;
Iwa rere wọn farasin,
Oluwa nikan l’o mọ.
- p Nwọn farasin fun wa, ṣugbọn
A kọ wọn s’iwe iye:
Igbagbọ, adurà, suru,
Lala on ‘jakadi wọn.
- mf Nwọn mọ̀ iṣura Rẹ lọhun;
Kà wa mọ́ wọn, Oluwa,
Nigbat’ O ba nṣiro ọṣọ,
Ti mbẹ lara ade Rẹ. Amin.