- f Wá k’a dà m’awọn ọ̀rẹ́ wa,
Ti nwọn ti jère na;
N’ ifẹ k’a f’ọkàn ba wọn lọ
Sode ọrun lọhun.
- K’awọn t’aiye d’orin wọn mọ́,
T’ awọn t’o lọ s’ogo;
Awa l’aiye, awọn l’ọrun,
Ọkan ni gbogbo wa.
- mp Idile kan n’nu Krist ni wa.
Ajọ kan l’a si jẹ;
di Iṣàn omi kan l’o yà wa.
p Iṣàn omi iku.
- f Ẹgbẹ ogun kan t’Ọlọrun,
Aṣẹ Rẹ̀ l’a si nṣe;
mp Apakan ti wọ́dò na ja,
p Apakan nwọ lọwọ!
- cr Ẹmi wa fẹrẹ dàpọ na,
Y’o gb’Ade bi ti wọn;
f Ao yọ̀ s’àmi Balogun wa,
Lati gbọ́ ipè Rẹ̀.
- cr Jesu, ṣọ wa, ṣ’amọna wa,
Gbat’ onikọ̀ ba de;
f Oluwa, pín omi meji,
Mu wa gunlẹ l’ayọ̀. Amin.