- mf F’ awọn enia Rẹ t’o lọ ‘simi,
Awọn ti o f’igbagbọ jẹwọ Rẹ,
f K’a yin orukọ Rẹ, Olugbala,
Alleluya!
- Iwọ l’apata wọn at’ odi wọn,
Iwọ ni Balogun wọn l’oju ‘jà,
cr Iwọ ni imọlẹ ókunkun wọn,
Alleluya!
- mp Jẹ ki awọn ọmọ-ogun Rẹ l’aiye,
cr Jagun nitoto b’awọn ti ‘gbani;
f Ki nwọn le ga ade ogo ti wọn,
Alleluya!
- Idapọ Ibukun wo l’o to ‘yi!
Awa nja nihin, awọn nyọ̀ lọhun!
Bẹ Tirẹ kanna l’awa at’ awọn.
Alleluya!
- mf Gbat’ ija ba ngbona, ti ogun nle,
p A dabi ẹni ngb’ orin ayọ wọn;
cr Igboiya a si de, at’ agbara.
Alleluya!
- p Ọjọ nlọ, orun wa fẹrẹ wọ̀ na,
Awọn ajagun toto y’o simi.
Didun ni isimi Paradise,
Alleluya!
- f Lẹhin eyi ọjọ ayọ kan mbọ̀,
Awọn mimọ yo dide n’nu gog;
Ọba ogo yio wà larin wọn.
Alleluya!
- ff Lat’ opin ilẹ, lat’opin okun,
Ogunlọgọ̀ nrọ́ wọ̀ ‘bode pearli;
Nwọn nyin Baba, Ọmọ, ati Ẹmi.
Alleluya! Amin.