Hymn 415: Who are these like stars appearing

Tal’ awon wonyi b’ irawo

  1. f Tal’awọn wọnyin t’irawọ,
    Niwaju itẹ mimọ,
    Ti nwọn si de ade wura,
    Ẹgbẹ ogo wo l’eyi?
    ff Gbọ́! Nwọn nkọ Alleluya,
    Orin iyìn Ọba wọn!

  2. mf Tali awọn ti nkọ màna,
    T’a wọ̀ l’aṣọ ododo?
    Awọn ti aṣọ funfun wọn
    Y’o ma funfun titi lai,
    Bẹni ki y’o gbó lailai:
    Nibo l’ẹgbẹ yi ti wa?

  3. p Awọn wọnyi l’o ti jagun,
    F’ọla Olugbala wọn;
    Nwọn jijakadi tit’ ikú,
    Nwọn kì b’ẹlẹṣẹ kẹgbẹ:
    cr Wọnyi ni kò sá f’ogun,
    f Nwọn ṣẹgun nipa Kristi.

  4. p Wọnyi l’ọkàn wọn ti gbọgbẹ,
    Ninu danwo kikorò;
    Wọnyi li o ti f’ adura,
    Mu Ọlọrun gbọ́ tiwọn;
    cr Nisisiyi nwọn ṣẹgun,
    Ọlọrun rẹ̀ wọn l’ẹkun.

  5. mf Awọn wọnyi l’o ti ṣọra,
    Ti nwọn fi ifẹ wọn fun Krist;
    Nwọn si y’ ara wọn si mimọ́,
    Lati sìn nigbagbogbo;
    f Nisisiyi li ọrun,
    Nwọn wà l’ ayọ̀ l’ọdọ Rẹ̀. Amin.