- mf F’ awọn enia Rẹ,
T’o ti f’ aiye silẹè;
Awọn t’o mọ̀ Ọ, t’o sin Ọ,
Gbà orin iyìn wa.
- F’ awọn enia Rẹ,
Gbà ohùn ọpẹ wa;
Awọn t’o fi Ọ s’ẹsan wọn,
f Nwọn kú n’ igbagbo Rẹ.
- mf Ni gbogbo aiye wọn,
‘Wọ ni nwọn nwò l’oju:
Ẹmi Mimọ́ Rẹ l’o nkọ́ wọn,
Lati s’ohun gbogbo.
- f Fun eyi, Oluwa,
cr A nyin orukọ Rẹ;
Jẹ k’a ma tẹlé iwà wọn,
di Ki a le kù bi wọn. Amin.