Hymn 413: Who are ye, who art His temple

Enyin wo ni tempili Re

  1. mf Ẹnyin wo ni tempili Rẹ̀,
    Oluwa t’a ti nreti;
    Woli ‘gbani ti sọ tẹlẹ;
    Ọlọrun m’ọ̀rọ Rẹ̀ ṣẹ;
    Awọn ti a ti ra pada,
    Yio fi ohùn kan yin.

  2. L’ apa wundia iya Rẹ̀,
    p Ẹ sa wo bi O ti sùn,
    T’ awọn alagba nì si nsìn,
    Ki nwọn to kú ‘nu gbagbọ:
    ff Halleluya, halleluya,
    W’ Ọlọrun Ọga-ogo.

  3. f Jesu, nipa ifihàn Rẹ,
    O ti gba iyà wa jẹ:
    Jọ, jẹ k’a ri ‘gbalà nla Rẹ,
    Mú ‘leri Rẹ ṣẹ si wa,
    Mù wa lọ sinu ogo Rẹ.
    Sọdọ Baba mimọ́ nì.

  4. ‘Wọ Alade igbala wa,
    K’ ifẹ Rẹ jẹ orin wa:
    Jesu, Iwọ l’a fiyin fun,
    Ni t’aiye t’O rà pada;
    Pẹlu Baba ati Ẹmi.
    Oluwa Ẹlẹda wa. Amin.