Hymn 412: Prepare O Sinner To Be Wise

Mura, elese, lati gbon

  1. f Mura, ẹlẹṣẹ, lati gbọ́n,
    Má duro de ọjọ ọla;
    Niwọ̀n b’o ti kẹgan ọgbọ́n,
    Bẹ l’o si ṣoro lati ri.

  2. mf Mura lati bere anu,
    Má duro de ọjọ ọla;
    Ki igbà rẹ ko má bà tán,
    p Ki ọjọ alẹ yi to tán.

  3. f Mura, ẹlẹṣẹ, k’o padà,
    Má duro de ọjọ ọla;
    p Nitori k’egun má ba ọ,
    K’ ọjọ ọla t’o to bẹrẹ̀.

  4. f Mura lati gbà Ibukun,
    Má duro de ọjọ ọla;
    p Ki fitila rẹ má ba ku,
    K’iṣẹ rere rẹ to bẹrẹ.

  5. f Oluwa, y’ẹlẹṣẹ padà,
    Ji kuro ninu were rẹ̀;
    Má jẹ k’o tàpa s’imọ̀ Rẹ,
    p K’o ma f’egbe rẹ se ‘lọra. Amin.