Hymn 411: Come unto Me, ye weary

Wa sodo mi, alare

  1. mf “Wa sọdọ mi, alarẹ̀,
    Ngo fun nyin n’isimi,”
    p A ! ohùn didun Jesu,
    Ti o p’ẹlẹṣẹ wá.
    cr O nsọ ti ore-ọfẹ,
    Ati t’alafia,
    Ti ayọ̀ ti kò lopin,
    T’ ifẹ ti kò le tàn.

  2. mf “Ẹ wá, ẹnyin ọmọ Mi,
    Ngo fun nyin n’ imọlẹ”
    p A! ohun ifẹ Jesu,
    cr Ti nle okunkun lọ;
    p Awa kun fun banujẹ,
    A ti s’ọ̀na wa nù;
    f Imọlẹ y’o m’ayọ̀ wà,
    Orọ y’o m’ orin wá.

  3. mf “Ẹ wà, ẹnyin ti ndàku,
    Ngo fun nyin ni iyè:”
    p Ohùn alafia Jesu,
    T’ o f’opin s’ija wa.
    mf Oju ọta wa korò,
    Ija si le pupọ;
    cr Ṣugbọn ‘Wọ fun wa n’ipá,
    f A bori ọta wa.

  4. mf “Ẹnikẹni t’o ba wá,
    Emi ki o ta nù;”
    p A! ohùn suru Jesu,
    cr T’o le ‘yemejì lọ!
    mf Ninu ifẹ iyanu,
    T’o p’ awa ẹlẹṣẹ,
    B’a tilẹ jẹ alaiye,
    S’ọdọ Rẹ, Oluwa. Amin.