- mf Ẹnyin ọmọ okú,
cr T’ o wà ninu ẹ̀ṣẹ;
Gbohun ihinrere,
Jesu ranṣẹ si nyin.
p Ẹnyin ẹni-egbe, b wá;
Ni apa Jesu àye mbẹ.
- Ẹ má pẹ titi mọ,
Má wá awawi mọ́;
O ni k’ ẹ wá loni,
Bo ẹ tilẹ̀ ‘toṣi;
Gbogbo nka ṣetan, ẹlẹṣẹ:
Fun gbogbo ọkàn, àye mbẹ.
- f Gbà ọ̀rọ t’ọrun gbọ́,
Ti oniṣẹ Rẹ̀ nsọ;
Alanu l’Oluwa,
Otọ l’orukọ Rẹ̀;
Ọkan iṣubu, pada wá,
S’ aigbẹkẹle nù, àye mbẹ.
- f Ẹnyin t’ ifẹ rẹ̀ fà,
Ẹ sunmọ ọdọ Rẹ̀,
Kristi t’oke pè nyin,
Ẹ gb’ohùn didùn Rẹ̀;
Ẹnikẹni t’o fẹ k’ o wá,
Ni aiya anu àye mbẹ. Amin.