- f Loni ni Jesu pè !
Aṣako, wá;
p A ! ọkàn òkunkun,
Má kiri mọ.
- f Loni ni Jesu pè !
Tẹtilelẹ;
Wolẹ fun Jesu, ni
Le ọ̀wọ yi.
- f Loni ni jesu pè !
Sa asalà;
p Iji igbẹsan mbọ̀,
cr Iparun mbọ̀.
- f Loni ni Ẹmi pè !
Jọ̀wọ ‘ra rẹ;
Má mu k’o binu lọ,
Sa anu ni. Amin.