- f Yara, ẹlẹṣẹ k’o gbọ́n,
Má reti ọjọ ọla;
Ọgbọn t’oke kilọ ọ,
p K’ o yanà iku silẹ.
- Yara tete wá anu,
Má reti ọjọ ọla;
Akoko rẹ le kọja,
K’ iṣẹ alẹ yi to tan.
- f Yara, ẹlẹṣẹ pada,
Má reti ọjọ ọla;
mp Ki fitila rẹ to kú,
K’ iṣẹ igbala to tán.
- f Jesu, y’ ẹlẹṣẹ pada,
Ji kuro nin’orun rẹ̀;
Má jẹ k’o ko ìpe Rẹ,
K’o má ba r’ibinu Rẹ. Amin.