- mp Ẹmi ọkàn wa npè,
O np’ẹlẹṣẹ k’o wa;
‘Yawo, Ijọ Kristi si npè,
K’ awọn ọmọ rẹ̀ wá.
- f Jẹ k’ẹni t’ o gbọ́, wi
F’ awọn t’o yika, wá;
Ẹnit’ ongbẹ ododo ngbẹ,
K’ o wá sọdọ Kristi.
- Lotọ; ẹni t’o fẹ,
Jẹ ki o wá l’ ọfẹ,
K’o mu omi iyè l’ọfẹ,
Jesu l’o pe k’o wá.
- f Gbọ́ bi Jesu ti npè,
ff Wipe, mo mbọ̀ kànkán;
Bẹni, Jesu mo nreti Rẹ,
Ma bọ̀ Olugbala. Amin.