- Ẹnyin t’ongbẹ ngbẹ, ẹ wá mu
Omi iye ti nṣàn;
Lati orisun ti Jesu,
Laisanwo l’awa nbu.
- p Wò ! b’o ti pẹ́ to t’ ẹ ti nmu
Ninu kanga eké,
T’ẹ nl’ agbara at’ ogùn nyin
cr Ninu nkan t’o nṣegbé.
- Jesu wipe, iṣura mi
Kò lopin titi lai;
f Yio f’ilera lailai fun
awọn t’o gbọ́ Tirẹ̀. Amin.