- mf Tirẹ l’lọla Baba,
O wà n’ ikawọ Rẹ;
B’ ojum’ ọla si mọ́ ba ni,
Nipa aṣẹ Rẹ ni.
- Akoko yi nfò lọ,
O ngbe ẹmi wa lọ;
Oluwa, mu ‘ranṣẹ Rẹ gbọ́n,
Ki nwọn lè wà fun Ọ.
- mp Akoko t’o nlọ yi,
L’ aiyeraiye rọ̀ mọ;
Fi agbara Rẹ Oluwa,
Ji agba at’ ewe.
- On kan l’a ba ma dù,
T’ a ba ma lepa rẹ̀;
Pe k’igba ‘bẹwò wa má lọ,
Laitun pada wá mọ.
- Jẹ k’a sa tọ Jesu,
K’ a si sure tete;
K’ ẹmi wa má ba kú, l’ o rì
p S’ okun biribiri. Amin.