mf Nigbat’ idanwo yi mi ka, p Ti idamu aiye mu mi; T’ọta f’ ara haǹ bi ọrẹ Lati wa iparun fun mi; f Oluwa jọ, má ṣ’ aìpè mi B’o ti pè Adam nin’ ọgbá di Pe, “Nibo l’o wa” ẹlẹṣẹ? Ki nle bọ́ ninu ẹbi na.
f Nigbat’ Eṣu n’nu ‘tanjẹ rẹ̀ Gbe mi gori òke aiye, T’o ni ki ntẹriba fun on, K’ohun aiye le jẹ temi. f Oluwa jọ, &c.
f ‘Gbat’ ogo aiye ba fẹ fi Tulàsi mu mi rufin Rẹ; T’o duro gangan lẹhìn mi; Ni ileri pe, “Kò si nkan.” f Oluwa jọ, &c.
Nigba igbẹkẹle mi Di t’ogùn ati t’ òriṣa; T’ ògede di adurà mi, Ti ọfọ̀ di ajisà mi. Oluwa jọ, &c.
Nigbati mo fẹ lati rìn L’ adamọ̀ at’ ifẹ ‘nu mi, T’ ọkàn mi nṣe hilàhílo, Ti nkò gbona, ti nkò tutu, Oluwa jọ, &c.
p Nigba mo sọnu bi aja, L’aigbọ ifère ọdẹ mọ; Ti nkò nireti ipada, Ti mo npàfọ ninu ẹ̀ṣẹ. Oluwa jọ, &c.
Nigbati kò s’ alabarò; Ti olutunu sì jìna; p T’ ibinujẹ, n’ ìji lile, cr Tẹ̀ ori mi ba n’ ironu. f Oluwa jọ, má ṣ’ aìpè mi B’o ti pè Adam nin’ ọgbá di Pe, “Nibo l’o wa” ẹlẹṣẹ? Ki nle bọ́ ninu ẹbi na.