- f Ọjọ nsure, o nkọja:
p Iku nsure, o de tan ;
cr Ẹlẹṣẹ nṣàwàda ni !
p Ọjọ at’ iku nwò ọ.
- Ẹmi nsure, t’o ba pin,
cr ‘Wọ kò le pada mọ̀ --- lai:
‘Wọ o bọ s’ainipẹkun;
Kò ha yẹ k’ iwọ ronu?
- f Ọlọrun ngbọ́, gbadura,
Ki ìgba rẹ to kọja;
K’Itẹ ‘dajọ Rẹ̀ to de,
K’ anu to tan, k’ ẹsan de.
- mf Mura giri, iku mbọ̀,
B’o ba duro, o ṣegbe;
di Ma sùn mọ̀, dide, sare;
Olugbala nreti rẹ. Amin.