Hymn 401: “Yet there is room”: the Lamb’s bright hall of song

Aye si mbe! ile Odagutan

  1. f “Àye ṣi mbẹ!” ile Ọdagutan,
    Ẹwà ogo rẹ̀ npè ọ pe, “Ma bọ̀.”
    p Wọle, wọle, wọle nisisiyi.

  2. Ọjọ lọ tan, orun sì fẹrẹ wọ̀,
    Okunkun de tan, ‘mọlẹ nkọja lọ:
    p Wọle, wọle, wọle nisisiyi.

  3. Ile ìyawo na kun fun àse!
    f Wọle, wọle, tọ̀ Ọkọ-‘yawo lọ:
    cr Wọle, wọle, wọle nisisiyi.

  4. f “Aye ṣi mbẹ!” ìlẹkun ṣi silẹ,
    Ilẹkun ifẹ; iwọ kò pẹ jù.
    p Wọle, wọle, wọle nisisiyi.

  5. f Wọle! wọle! tirẹ ni àse na,
    Wà gb’ẹ̀bun ‘fẹ aiyeraiye lọfẹ!
    p Wọle, wọle, wọle nisisiyi.

  6. f Kiki ayọ̀ l’o wà nibe; wọle!
    Awọn angẹli npè ọ fun ade,
    p Wọle, wọle, wọle nisisiyi.

  7. f Lohùn rara n’ ipè ifẹ na ndún!
    Wá, mà jafara, wọle àse na.
    p Wọle, wọle, wọle nisisiyi.

  8. ff O nkún! O nkún ! ile ayọ̀ na nkún !
    cr Yara ! maṣe pẹ, kò kún jù fun ọ.
    p Wọle, wọle, wọle nisisiyi.

  9. p K’ ilẹ to ṣu, ilẹkun na le tì!
    p ‘ Gbana, o k’ abamọ́! “Oṣe ! Oṣe !”
    cr Oṣe ! Oṣe ! kò s’ àye mọ́, oṣe ! Amin.