Hymn 400: O where shall rest be found

Nibo n’ isimi wa

  1. mf Nibo n’ isimi wà
    ‘Simi f’ọkàn arẹ̀?
    Lasan l’a wa s’opin okun,
    Ati s’opin ilẹ.

  2. Aiye kò le fun ni
    N’isimi ti a nfẹ;
    K’a le pẹ titi aliye kọ!
    p K’a sì tète ku kọ!

  3. Aiye kan mbẹ lokè,
    T’o jinnà s’ aiye yi,
    Nwọn kò nṣirò ọdun nibẹ;
    Ifẹ ni aiye na!

  4. p Iku mbẹ, apá rẹ̀
    Kawọ emì wa yi;
    pp B’ irora kikoro ti to
    cr Ninu iku keji!

  5. f Ọlọrun, jọ kọ́ wa
    p K’a sa fun iku yi;
    K’a má bà lé wa lọdọ Rẹ,
    K’a sì ṣegbe lailai.

  6. Nihin l’ẹ̀bẹ wa mọ!
    Aiye ifẹ pipe,
    Ati isimi ailopin
    Wà ninu Rẹ nikan. Amin.