- mf Iwọ t’o nmu ọkàn mọlẹ’
Nipa ‘mọle atọrunwa,
di T’o si nsẹ ìri ibukun
Sor’ awọn ti nṣafẹri Rẹ.
- mf Jọ maṣai fi ibukun Re,
Fun olukọ at’akẹko;
Ki ijọ Rẹ le jẹ mimọ,
K’ atupa rẹ̀ ma jò gere.
- F’ọkàn mimọ fun olukọ
Igbagbọ, ‘reti, at’ ife;
Ki nwọn j’ẹnit’ Iwọ ti kọ́
Ki nwọn le j’olukọ rere.
- F’eti igbọràn f’akẹkọ,
Ọkan ‘rẹlẹ at’ailẹtan;
Talaka to kun f’ẹbùn yi
Sàn ju ọba aiye yi lọ.
- cr Buk’ oluṣọ; buk’agutan,
Ki nwọn j’ọkan labẹ ‘ṣọ Rẹ;
Ki nwọn ma f’ọkan kan ṣọna
Tit’aiye oṣi yi y’o pin.
- Baba, b’awa ba n’ore Rẹ,
Laiye yi l’a o ti l’ogo;
K’a to kọja s’ oke ọrun
L’ao mọ ohun ti aikú jé. Amin.