- mf Oluwa mi, mo njade lọ,
Lati ṣe iṣẹ ojọ mi;
Iwọ nikan l’emi o mọ̀
L’ ọrọ, l’erò, ati n’ iṣe.
- Iṣẹ t’o yan mi, l’ anu Rẹ,
Jẹ ki nlè se tayọtayọ;
Ki nr’ oju Rẹ ni iṣẹ mi,
K’ emi si lè f’ ìfẹ Rẹ han.
- Dabobò mi lọwọ ‘danwo,
K’ o pa ọkàn mi mọ kuro
L’ ọwọ aniyan aiye yi,
Ati gbogbo ifẹkufẹ.
- Iwo t’oju Rẹ r’ọkàn mi,
Ma wà lọw’ ọtùn mi titi,
Ki mma ṣiṣẹ lọ l’aṣẹ Rẹ,
Ki nf’ iṣẹ mi gbogbo fun Ọ.
- Jẹ ki nrẹrù Rẹ t’o fuyẹ,
Ki mma ṣọra nigbagbogbo;
Ki mma f’oju si nkan t’ ọrun,
Ki nsì mura d’ọjọ ogo.
- f Ohunkohun t’o fi fun mi
Jẹ ki nle lò fun ogo Rẹ:
Ki nfayọ̀ sure ije mi;
Ki mba Ọ rìn titi d’ọrun. Amin.