- mp Ẹ wá s’apakan, k’ẹ simi diẹ,
Mo mọ̀ arẹ̀ ati wahala nyin,
E nù ogùn oju nyin nù kuro,
cr K’ẹ tun gb’agbara n’nu agbara Mi.
- mp Ẹ takétè s’ohun adùn aiye,
Ẹ wá fun idapọ̀ t’aiye kò mọ̀,
Ẹ nikan wà lọdọ Mi on Baba,
Lọdọ Mi on Baba ẹgbẹ nyin kún.
- Ẹ wa sọ gbogb’ ohun t’ẹ ṣe fun mi,
Sọ t’iṣẹgun ati t’iṣubu nyin,
p Mo mọ̀ b’iṣẹ èmi ti ṣoro to,
cr Ade t’o dara t’on t’omije ni.
- mp Ẹ wa simi; àjo na jìn pupọ̀,
Arẹ o mu nyin, ẹ o ku l’ọna;
cr Onjẹ ìye wà nihin, ẹ wa jẹ,
Nihin l’omi ìye wa, ẹ wa mu.
- Jade l’ọtun lat’ ọdọ Oluwa,
Ẹ pada lọ ṣiṣẹ titi ṣulẹ:
Ẹ kò padanu wakati t’e lò
F’ẹkọ mi ọi, at’ isimi ọrun. Amin.