- Emi at’ ara ile mi,
Yio ma sin Oluwa wa;
Ṣugbọn emi papa;
Yio f’iwa at’ ọrọ hàn,
Pe mo mọ̀ Oluwa t’ọrun,
Mo nfọkàn totọ sìn.
- Em’ o f’ apẹrẹ ‘re le’lẹ;
Ngo mu idena na kuro;
Lọdọ ọm’ọdọ mi;
Ngo f’iṣẹ wọn hàn n’iwà mi,
Sibẹ n’nu ‘ṣẹ mi ki nsi ni
Ọla na ti ifẹ.
- Emi ki y’o ṣoro gb’ ipẹ̀,
Emi ki y’o pẹ tù ninu,
Ọm’ ẹhin Ọlọrun;
Mo si fẹ jẹ ẹni mimọ́,
Ki nsi fa gbogbo ile mi,
S’oju ọna ọrun.
- Jesu, b’O ba da ‘na ‘fẹ na,
Ohun èlo t’Iwọ fẹ lò,
Gbà s’ọwọ ara Rẹ!
Ṣiṣẹ ifẹ rere n’nu mi,
Ki nfi b’ onigbagbọ totọ
Ti ngbe l’aiye hàn wọn.
- Fun mi l’ore-ọfẹ totọ,
Njẹ! Emi de lati jẹri
‘Yanu orukọ Rẹ,
Ti o gbà mi lọwọ ègbé;
Ire eyi t’a mọ̀ l’ọkàn,
Ti gbogb’ ahọn le sọ.
- Emi t’o bọ́ lọwọ ẹṣẹ,
Mo wá lati gba ‘le mi là,
Ki nwasu ‘daríji;
F’ọmọ, f’aya, f’ọmọ-dọ mi,
Lati mu wọn ‘nà rere
Lọ si ọrun mimọ́. Amin.