- Ọlọrun ọgbọn at’ ore,
Tan ‘mọlẹ at’ otọ,
Lati f’ọna toro hàn wa,
Lati tọ́ ‘ṣisẹ wa.
- Lati tọ ‘pa wa n’nu ewu,
Li arin apata;
Lati ma rìn lọ larin wọn,
K’a m’ọkọ wa gunlẹ.
- B’ o’r ọfẹ Rẹ ti nmu wa yẹ,
K’a kọ́ wọn b’ ẹkọ Rẹ,
A wá lati tọ ọmọ wa
Ni gbogbo ọ̀na Rẹ.
- Li akoko, pa ifẹ wọn,
On ‘gberaga wọn run;
K’a fi ọna mimọ hàn wọn,
Si Olugbala wọn.
- A fẹ wòke nigbakugba,
K’ a tọ apẹrẹ Rẹ;
K’a rú ‘bẹru, on ‘reti wọn,
K’a tun ero wọn ṣe.
- A fẹ rọ̀ wọn lati gbagbọ,
Ki nwọn f’ itara hàn;
Ki a maṣe lo ikanra,
‘Gbat’ a ba le lo’ fẹ.
- Eyi l’a f’igbagbọ berè,
Ọgbọn t’o t’oke wa;
K’a f’ẹ̀ru ọmọ s’aiya wọn,
Pẹlu ifẹ mimọ́.
- K’a ṣọ ‘fẹ wọn ti ntẹ̀ s’ibi,
Kuro l’ọ̀na ewu;
K’a fi pẹlẹ tẹ̀ ọkàn wọn,
K’a fà wọn t’ Ọlọrun. Amin.