- f Funrugbin lowurọ,
Má simi tit’ alẹ;
F’ẹ̀ru on ‘yemeji silẹ,
Ma fun sibi-gbogbo.
- mf ‘Wọ kò mọ̀ ‘yi ti nhù,
T’orọ̀ tabi t’alẹ:
Ore-ọfẹ yio pa mọ,
‘Bit’ o wù k’o bọ́ si.
- Yio sì hu jade
L’ẹwà tutu yọ̀yọ,
Bẹni y’o sì dagba soke,
Y’o s’eso nikẹhìn.
- ‘Wọ k’ y’o ṣiṣẹ lasan!
Ojo, ìri, orun,
cr Yio jumọ ṣiṣẹ pọ̀
Fun ìkore ọrun.
- f Njẹ nikẹhìn ọjọ,
Nigbat’ opin ba de,
ff Awọn Angẹl’ y’o sì wa ko
Ikore lọ sile. Amin.