- mf Jesu, maṣe jẹ k’a simi,
Tit’ O fi d’ọkàn wa:
T’ O fun wa ni ‘balẹ aiya,
T’ O wó itẹ́ ẹṣẹ
- A ba lè wo agbelebu,
Titi iran nla na
Yio sọ ohun aiye d’ofo,
T’ y’o mu ‘banujẹ tan.
- Tit’ ọkàn wa yio goke,
T’ ao bọ́ lọwọ ara,
T’ ao fi r’alafia pipe,
Ati ayọ̀ ọrun.
- Bi a si ti ntẹjumọ Ọ,
K’ a d’ọ̀kan pẹlu Re;
K’ a si ri pipe ẹwà Rẹ,
N’ ile ayọ loke. Amin.