- Wá, ma ṣiṣẹ.
f Tani gbọdọ s’ọlẹ ninu oko,
‘Gbati gbogbo enia nkorè jọ?
Kaluku ni Baba paṣẹ fun pe,
“Ṣiṣẹ loni.”
- Wá, ma ṣiṣẹ.
Gbà ‘pe’ giga ti angẹli ko ni---
Mu ‘hinrere tọ t’àgbà t’ewe lọ:
di “Ra ‘gbà pada;” wàwà l’akoko nlọ,
p Ilẹ ṣú tan.
- mf Wá, ma ṣiṣẹ.
Oko pọ, alagbaṣe kò si to,
cr A n’ibi titun gbà, a ni ‘pò ‘rọ́;
Ohùn ọ̀nà jijin, at’itosi,
Nkigbe pe, “Wa.”
- f Wá, ma ṣiṣẹ.
Le ‘yemeji on aigbagbọ jinna,
Kò s’alailera ti kò le ṣe nkan:
di Ailera l’Ọlọrun ama lò jù
Fun ‘ṣẹ́ nla Rẹ̀.
- cr Wá, ma ṣiṣẹ.
‘Simi kò si, nigbat’ iṣe ọsan,
Titi orùn yio fi wọ̀ l’alẹ,
f Ti awa o si gbọ ohùn ni pe,
“O ṣeun, ọmọ.”
- Wá, ma ṣiṣẹ.
Lala na dùn, èrè rẹ̀ si daju.
cr ‘Bukun f’awọn t’o f’ori ti d’opin;
Ayọ̀ wọn, ‘simi wọn, y’o ti pọ̀ to.
p Lọd’ Oluwa! Amin.