mf Tan ‘mọlẹ Rẹ si wa Loni yi Oluwa; Fi ara Rẹ hàn wa N’nu ọrọ Mimọ Rẹ; Jọ m’ọkan wa gbona, K’ a ma wo oju Rẹ, K’ awọn ‘mọde le kọ Iyanu ore Rẹ.
mp Mí si wa Oluwa, Ina Ẹmi Mimọ, cr K’a le fi ọkàn kan Gbe orukọ Rẹ ga; Jọ fi eti igbọ, At’ ọkàn ironu, Fun awọn ti a nkọ, L’ ohun nla t’O ti ṣe.
mf Ba ni sọ, Oluwa, Ohun to yẹ k’a sọ, Gẹgẹ bi ọrọ Rẹ, Ni ki ẹkọ wa jẹ; K’awọn agutan Rẹ, Le ma mọ ohùn Rẹ, Ibit’ O ntọ́ wọn si, cr Ki nwọn ọiọ le ma yọ̀.
mf Gbe ‘nu wa, Oluwa, K’ifẹ Rẹ je tiwa, Iwọ nikan lao fi Ipa wa gbogbo sin; K’iwa wa jẹ ẹkọ. Fun awọn ọmọ Rẹ, di K’o si ma kede Rẹ, Ninu gbogbo ọkàn. Amin.