- mf Gb’ agbelebu rẹ, ni Krist wi,
B’o ba fẹ ṣ’ ọmọ-ẹhin Mi;
Sẹ ‘ra rẹ, kọ̀ aiye silẹ,
Sì ma f’ìrẹlẹ tẹle Mi.
- Gb’agbelebu rẹ, má je ki
Iwuwo rẹ̀ fò ọ laìya:
cr Ipa Mi y’o gb’ ẹmi rẹ ró,
Y’o m’ọkàn at’apa rẹ le.
- mf Gb’agbelebu rẹ, má tiju,
Ma jẹ k’ọkàn wère rẹ kọ̀;
p Oluwa ru agbelebu,
Lati gbà ọ lọwọ iku.
- mf Gb’agbelebu rẹ, n’ipá Rẹ̀
Rọra ma là ewu ja lọ;
cr Y’o mu ọ de ilẹ ayọ̀;
Y’o mu ọ ṣẹgun iboji.
- mf Gb’agbelebu rẹ, ma tẹle,
Màṣe gbe silẹ tit’iku;
Enit’ o rù agbelebu,
cr L’o lè reti lati d’ade.
- mf ‘Wọ Ọlọrun Metalọkan,
L’a o ma yìn titi aiye;
Fun wa, k’a le ri n’ile wa.
Ayọ̀ ọrun ti kò lopin. Amin.