Hymn 390: I gave My life for thee

Mo f’ara Mi fun o

  1. mf Mo f’ara Mi fun ọ,
    Mo kú nitori rẹ,
    cr Ki nlè rà ọ pada,
    K’o lè jinde nn’òku;
    p Mo f’ara mi fun ọ,
    Kini ‘wọ ṣe fun Mi?

  2. mp Mo f’ọjọ aiye Mi
    Ṣe wàhalà fun ọ;
    cr Ki iwọ bà lè mọ̀
    Adùn aiyeraiye;
    p Mo lo ọpọ ‘dun fun ọ,
    O lò kan fun mi bi?

  3. f Ile ti Baba Mi
    At’ itẹ́ ogo Mi;
    di Mo fi silẹ w’aiye;
    Mo d’alarinkiri:
    p Mo f’ilẹ tori rẹ,
    Ki l’o f’ilẹ fun Mi?

  4. Mo jiya pọ̀ fun ọ,
    Ti ẹnu kò le sọ;
    Mo jijakadi nla,
    ‘Tori igbala rẹ;
    mp Mo jiya pọ̀ fun ọ,
    O lè jiya fun Mi?

  5. mf Mo mu igbala nla,
    Lat’ile Baba Mi
    cr Wa, lati fi fun ọ;
    Ati idariji;
    Mo m’ẹbun wá fun ọ,
    p Kil’o mu wá fun Mi.

  6. f Fi ara rẹ fun Mi,
    Fi aiye rẹ sìn Mi;
    Diju si nkan t’aiyem
    Si wò ohun t’ọrun;
    Mo f’ara Mi fun ọ,
    Si f’ara rẹ fun Mi. Amin.