p Ọkàn arẹ̀, ile kan mbẹ, L’ọn jinjin s’aite ìṣẹ́; Ile t’ayida kò le de, Tani kò fẹ simi nibẹ? f Duro . . . . rọju duro, máṣe kùn! cr Duro, duro, sa rọju, máṣe kùn!
p Bi wahala bò ọ mọlẹ, B’ipin rẹ laiye ba buru, W’oke s’ile ibukun na; Sa rọju duro, màṣe kùn! f Duro, &c.
mp Bi ẹ̀gún ba wà lọnà rẹ, Ranti ori t’a f’ẹ̀gún de; p B’ibanujẹ b`` ọkàn rẹ, O ti ri bẹ f’Olugbala. f Duro, &c.
f Ma ṣiṣẹ lọ, máṣe rò pe, A kò gb’adurà ẹ̀dun rẹ; Ọjọ isimi mbọ̀ kànkán: Sa rọju duro, máṣe kùn! f Duro . . . . rọju duro, máṣe kùn! Duro, duro, sa rọju, máṣe kùn! Amin.